Ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́

By Fẹ́mi Akínṣọlá

Hun! Kín ló dé

Ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́

Kín ló ń kán ọ lójú

Kín lo fẹ́ gbà

Irú ebi kín ló ń pa ọ́

Tó ò lé mébi mọ́nú

Kín ló dé tó ò mójú nù

Kín ló dé tó ò le yááfí

Kín ló dé tó lè ṣàpamọ́ra

Kín lo fi ń sọrí

Tó o fi gbẹ̀mí ìràwọ̀ àṣẹ̀ṣẹ̀yọ

Tó o fi wólé ọlá kanlẹ̀ lógìdo

 Tó o fi sọ̀kò ọ̀fọ̀ sílé aláyọ̀

Tó o fi dáṣọ ìbànújẹ́ dípò ìdùnú

Iṣẹ́ kín ló jẹ́ fún Kọ́lá

 Àrọwà wo lo fi tù ú lójú

 T’ọmọ Ọládàpọ̀ fi jẹ́ ọ ní hòo!

KỌ́LÁ  ÒÒÒÒ!

Hàààà! KỌ́LÁ

Kín  gan ló wọ̀ ọ́ lójú nílé ikú?

Ọjà wo gan ló wá títí

Tó o fi já sílé ikú dandan

Láníntán kan kìí níwo ẹṣin

Mo gbà  láì janu

À mọ́ tó bá jẹ́ ti ọgbọ́n

Èdùwà fún lọ́gbọ́n

Tó bá jẹ́ ti ìmọ̀

Adániwáyé Ò gan ìmọ̀ fún ọ dénú agbárí

Bá a bá ń perí làákàyè baba ọgbọ́n

Bì ibú omi ni nínú agbárí Kọ́lá Ọládàpọ̀

Ẹ̀mì ìtẹríba níbi gbogbo

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ dójútáyé

Ká ṣọ̀yàyà nínú ìfẹ́ dódò ikùn

Ká gbani nímọ̀ràn àtàtà ká sì tẹ́ti bẹ̀lẹ̀jẹ́

Kọ́lá  Ọládàpọ̀ ò lábùyẹ

Báyé bá rí ẹni ẹni tó kú

Ẹ bí Kọ́lá ,ẹ pé irọ́ ni mo pa

 Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́

Ó tó torí tá a bá ṣèdárò ẹni wa

Ilẹ̀ ń gbé èèyàn mi

Kọ́lá  Ọládàpọ̀ ti dáṣọrọ̀gún

Olórí dúkìá mí kanlẹ̀

Kọ́lá  Ọládàpọ̀ bó sọnù ẹ̀mi ò ṣe é rí he bí owó

Láwújọ akọ̀ròyìn kàròyìn

Kọ́lá ti pà ‘lẹ̀kùn ìmọ̀ dé

Kọ́lá  pàlẹ̀kùn ìmọ̀ dé

 pẹ̀lú àgádágodo láéláé gbére

Ìràwọ̀ tó ń tàn níṣẹ́ ìròyìn Kọ́lá darapọ̀ máwùjọ ẹbọra

A ṣìpẹ̀  ṣìpẹ̀ kíkú ó jọ̀wọ́ ẹ̀

Àlọ̀ lá rí Kọ́lá lọ kò náání àbọ̀.

Ẹni  tó bá mọ ilé agbe

Kó bá ni wò ó

Ṣé ó tún ń dá aró bí ìsaájú?

Ẹni  tó bá mọ ilé àlùkò kó bá ni wò ó

Ṣó sì ń ṣe osùn láì rẹ̀wẹ̀sì?

Èèyàn tó bá mọ ilé lékeǹké ó wí

Ṣé ò tẹ̀tì nínú ìkẹfun?

Eyín ká ilé

Ilé ẹ̀rín wó wómúwómú

Ẹyẹ lọ ìtẹ́ dòfò ó dòfo

Aya,ọmọ, ẹbí, ọ̀rẹ́, ìyekan

Ewúrẹ́ wọn bojú wò réré

Gbogbo wọn dúró gbári

Wọn ò réléèpo

Àgùtàn wọn bojú wò réré

Gbogbo wọn dúró gbári

Wọ́n fi eléèrí ṣàpèdáhùn

Kọ́lá  Ọládàpọ̀ ò sí mọ́

Ikú ti jàwá lólè sùúná tuntun

 Òkú ló jìírọ̀ orúkọ ọmọ

Kọ́lá ò dà pọ̀ mọ́ lá mọ́

Òṣùpá Kọ́lá wọ́ọ̀kùn

Bàtá Ọlá jákùn ó dìkàlẹ̀

Bá a bá tún gbìyànjú tomi lójú  títí bí egbére

Ṣá  a rómi ojú rojọ ṣèràpadà ẹ̀mí Kọ́lá bí

Bá  a bá ràròkàn dé góǹgó ẹ̀mí

Ẹ gbọ́ ṣé ikú fojú ibẹ̀ ṣọ̀fọ̀ di ẹ̀rín

Ẹni a ròyìn ròyìn tí tí tí

nílànà àlà funfun bí aṣọ

Ẹ jẹ́ á ṣè wọ̀n láròyé

Ẹ jẹ́ á ṣè wọ̀n ní ìwíjọ́

Ẹ jẹ́ á yin Èdùwà

Ikú ló jẹ̀bi

Ìkú ti gbó tayọ ewú

Ikú ti gbó tayọ òǹkà

Ikú ti gbó tayọ ìdùnú

Ikú  ń fìbànújẹ́ ṣe ayọ̀  ọ́ yọ̀ ni

Ikú lèèyàn tó dáná sunlé ìran rẹ̀ tẹ̀rín tọ̀yàyà

Ìránṣẹ́ ni gbogbo ajogun

 Èdùwà Ó ṣèdájọ́ ikú

Lorí èyí Èdùwà ó gbẹ̀san ikú Kọ́lá fún wa

Ọmọ tí Kọ́lá  Ọládàpọ̀ bí

kí gbogbo wọn pátá ò yàn ,kí wọn ó gbó hewú gbúrúgbúrú

Kí ẹ̀mí ìyàwó ó gùn, kí ẹbí,ọ̀rẹ́,ìyekan ó yọjú

ṣàjọyọ̀ nínú ìṣerere

Ọmọ tó fi sáyé lọ

A bèèrè ẹ̀san èyí Èdùwà

Ẹ̀bẹ̀ kan túnrè é

Má wo gbogbo ibi orí Kọ́lá  Ọládàpọ̀ ti mì ní dúníyàn

gbégi lé ‘dùnú ẹ̀ ní párádísè

Àànú la bèèrè má wo àlésọ̀ wa bí ẹlẹ́ran ara.

*Fẹ́mi Akínṣọlá kí ọ pé, ó dàárọ̀ gbére, Kọ́lá Ọládàpọ̀ ,Mr Nice Guy  Lagelu FM.*


Comments

Leave a comment